E fori ji mi
From Wikipedia
̣̣==1 Ẹ FORÍ JÌ MÍ==
- Mo mọ̀ pé tẹ́ ẹ bá rèyìí
- Mo mọ̀ póhun tẹ́ ó bèèrè
- Ni pé
- Ta ni ń jẹ́mi?
- Ta lèyí tó ń tẹlẹ̀ sùàsùà 5
- Ẹ dákun ẹ má bínú
- Ẹ fiyè désàlẹ̀ ikùn
- Ọmọdé ni mo jẹ́, n ò sòyájú
- Ìdánwò ni mo gbà, ẹ yé bá mi gbà á bẹ́ẹ̀
- N ò kúkú mọbẹ̀ẹ́ sè
- Ẹ má bínú pé ó láta 10
- Àwọn àgbà ló bẹ̀mí ńsé
- Mo sì se kí n sá
- Sùgbọ́n ẹni tí Aláàfin bẹ̀ níṣẹ́ ni
- Tódò Ọbà sì kún
- Ìrònú di méjì, ká bomi sẹ́nu fẹ́ná 15
- Iná ò gbọdọ̀ kú, omi ò gbọdọ̀ dànù
- Odò ọbà sòroó kán lù
- Isẹ́ ọ̣ba sòroó sàijẹ́
- Ni mo se se bí òjísẹ́ náà se se
- Mo ní kí á fìyànjú se gbígbà 20
- Pé bí ó bá kù díè káàtó
- Kẹ́ ẹ bá mi tún un se
- Bó sì se gbígbà bẹ́ẹ̀ náà ni
- Kẹ́ ẹ bá mi gbà á bẹ́ẹ̀
- Kẹ́ ẹ̣ bá mi fi mọ́ra 25
- Kọ́rọ̀ wá dàbí isó inú ẹ̀kú
- Kẹ́ ẹ bá mi se é ní àgìdímọ̀làjà, awo Ifẹ̀
- Níbi tí àwọn awo ti ń se ìgbọ̀wọ́ ara wọn
- Tí títẹ́ sì jìnà sáwoo wọn tèfètèfè
- Tọ́rọ̀ wáá dà bí ọmọ babaláwo 30
- Tí babaa rẹ̀ dolóògbé
- Lọmọ bá bọ́ síwájú àwọn awo
- Ló yílè sọ́tùn-ún, ló yílẹ̀ sósì
- Ló figbe bọnu, ló ń ké tantan
- Ó lóun ò mọ̀dá ọwọ́ 35
- Òun ò mọ̀kẹrẹrẹ ẹbọ íha
- “Ẹwáá bá mi tọ́rọ̀ yí se o, ẹ̀yin àgbà”
- Njẹ́ àbọ̀ mi rè é o
- N ò mọ̀kan
- N ò mọ̀kàn 40
- Ẹ dákun ẹ́ bá mi gbà á bẹ́ẹ̀
- Kẹ́ ẹ fìyókù sàforíjìì mi